“Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ, èmi kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ mi pamọ́. Mo wí pé, ‘Èmi yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,’ ìwọ sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.”
Dáfídì dẹ́kun fífi ara pamọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wòsàn. Nígbà tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Ọlọ́run kò dójútì í. Ó dáríjì í. Yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ. Kò sí ìbòjú mọ́. Mú ìdààmú rẹ wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Yóò sì pààrọ̀ rẹ̀ fún àánú.
Gba awọn iṣẹlẹ tuntun wa pẹlu iwunilori
akoonu imeli nigbagbogbo