“ Ẹ má ṣe ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ìbéèrè yín di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju gbogbo òye lọ, yóò sì máa ṣọ́ ọkàn àti èrò inú yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”
Ṣé o ń ṣàníyàn? Bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà. Dípò kí o máa bẹ̀rù, fi ohun gbogbo lé Ọlọ́run lọ́wọ́. Pẹ̀lú ọpẹ́, ṣí ọwọ́ rẹ àti ọkàn rẹ. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí àlàáfíà Rẹ̀ máa ṣọ́ ọkàn àti èrò inú rẹ bí odi.
Gba awọn iṣẹlẹ tuntun wa pẹlu iwunilori
akoonu imeli nigbagbogbo